Tẹsalonika Kinni 5:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ̀yin ará, kò nílò pé a tún ń kọ̀wé si yín mọ́ nípa ti àkókò ati ìgbà tí Oluwa yóo farahàn.

2. Nítorí ẹ̀yin fúnra yín ti mọ̀ dájú pé bí ìgbà tí olè bá dé lóru ni ọjọ́ tí Oluwa yóo dé yóo rí.

3. Nígbà tí àwọn eniyan bá ń wí pé, “Àkókò alaafia ati ìrọ̀ra nìyí,” nígbà náà ni ìparun yóo dé bá wọn lójijì, wọn kò sì ní ríbi sá sí; yóo dàbí ìgbà tí obinrin bá lóyún, tí kò mọ ìgbà tí òun yóo bí.

4. Ẹ̀yin ará, ẹ̀yin kò sí ninu òkùnkùn ní tiyín, tí ọjọ́ náà yóo fi dé ba yín bí ìgbà tí olè bá dé.

5. Nítorí ọmọ ìmọ́lẹ̀ ni gbogbo yín; ọmọ tí a bí ní àkókò tí ojú ti là sí òtítọ́, ẹ kì í ṣe àwọn tí a bí ní àkókò àìmọ̀kan; ẹ kì í ṣe ọmọ òkùnkùn.

Tẹsalonika Kinni 5