Tẹsalonika Kinni 3:7-13 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ará, ìròyìn yìí fún wa ní ìwúrí nípa yín, nítorí igbagbọ yín, a lè gba gbogbo ìṣòro ati inúnibíni tí à ń rí.

8. Nítorí pé bí ẹ bá dúró gbọningbọnin ninu Oluwa nisinsinyii, a jẹ́ pé wíwà láàyè wa kò jẹ́ lásán.

9. Nítorí pé ọpẹ́ mélòó ni a lè dá lọ́wọ́ Ọlọrun nítorí yín, lórí gbogbo ayọ̀ tí à ń yọ̀ nítorí yín níwájú Ọlọrun wa?

10. À ń gbadura kíkankíkan tọ̀sán-tòru pé kí á lè fi ojú kàn yín, kí á lè ṣe àtúnṣe níbi tí igbagbọ yín bá kù kí ó tó.

11. Ǹjẹ́ nisinsinyii, kí Ọlọrun Baba wa fúnrarẹ̀ ati Oluwa wa Jesu kí ó tọ́ ẹsẹ̀ wa sí ọ̀nà dé ọ̀dọ̀ yín.

12. Kí Oluwa mú kí ìfẹ́ yín sí ara yín ati sí gbogbo eniyan kí ó pọ̀ sí i, kí ó sì túbọ̀ jinlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí tiwa ti rí si yín.

13. Kí Oluwa fi agbára fun yín, kí ọkàn yín lè wà ní ipò mímọ́, láìní àléébù, níwájú Ọlọrun Baba wa nígbà tí Oluwa wa Jesu bá farahàn pẹlu gbogbo àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.

Tẹsalonika Kinni 3