8. Nítorí ẹ̀yin ni ẹ tan ìyìn rere ọ̀rọ̀ Oluwa káàkiri, kì í ṣe ní Masedonia ati Akaya nìkan, ṣugbọn níbi gbogbo ni ìròyìn igbagbọ yín sí Ọlọrun ti tàn dé. Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ní pé à ń sọ ohunkohun mọ́.
9. Nítorí wọ́n ń sọ bí ẹ ti ṣe gbà wá nígbà tí a dé ọ̀dọ̀ yín, ati bí ẹ ti ṣe yipada kúrò ninu ìbọ̀rìṣà, láti máa sin Ọlọrun tòótọ́ tíí ṣe Ọlọrun alààyè;
10. ati bí ẹ ti ń retí Jesu, Ọmọ rẹ̀, láti ọ̀run wá, ẹni tí a jí dìde ninu òkú, tí ó yọ wá kúrò ninu ibinu tí ń bọ̀.