Sefanaya 2:8-13 BIBELI MIMỌ (BM)

8. OLUWA ní: “Mo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ àbùkù tí àwọn ará Moabu ń sọ ati bí àwọn ará Amoni tí ń fọ́nnu, bí wọn tí ń fi àwọn eniyan mi ṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n sì ń lérí pé àwọn yóo gba ilẹ̀ wọn. Nítorí náà bí èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ti wà láàyè,

9. mo búra pé, a óo pa ilẹ̀ Moabu run bí ìlú Sodomu, a óo sì run ilẹ̀ Amoni bí ìlú Gomora, yóo di oko tí ó kún fún igbó ati ihò tí wọ́n ti ń wa iyọ̀, yóo di aṣálẹ̀ títí lae, àwọn eniyan mi tí ó kù yóo kó àwọn ohun ìní wọn tí ó kù.”

10. Wọn yóo sì gba ilẹ̀ wọn, ohun tí yóo dé bá wọn nìyí nítorí ìgbéraga wọn, nítorí pé wọ́n ń fi àwọn eniyan èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ṣe yẹ̀yẹ́. Wọ́n ń fi wọ́n fọ́nnu.

11. OLUWA óo dẹ́rùbà wọ́n, yóo sọ gbogbo oriṣa ilé ayé di òfo, olukuluku eniyan yóo sì máa sin OLUWA ní ààyè rẹ̀ ní gbogbo orílẹ̀-èdè.

12. Ẹ̀yin ará Etiopia, n óo fi idà mi pa yín.

13. Èmi OLUWA yóo dojú ìjà kọ ìhà àríwá, n óo pa ilẹ̀ Asiria run; n óo sọ ìlú Ninefe di ahoro, ilẹ̀ ibẹ̀ yóo sì gbẹ bí aṣálẹ̀.

Sefanaya 2