1. Èyí ni iṣẹ́ tí Ọlọrun rán Sefanaya, ọmọ Kuṣi, ọmọ Gedalaya, ọmọ Amaraya, ọmọ Hesekaya ní àkókò ìjọba Josaya, ọmọ Amoni, ọba Juda.
2. OLUWA ní, “N óo pa gbogbo nǹkan tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé run:
3. ati eniyan ati ẹranko, ati gbogbo ẹyẹ, ati gbogbo ẹja. N óo bi àwọn eniyan burúkú ṣubú; n óo pa eniyan run lórí ilẹ̀.
4. “N óo na ọwọ́ ibinu mi sí ilẹ̀ Juda, ati sí àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu. N óo pa gbogbo oriṣa Baali tí ó kù níhìn-ín run, ati gbogbo àwọn babalóòṣà wọn;
5. ati àwọn tí ń gun orí òrùlé lọ láti bọ oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀. Wọ́n ń sin OLUWA wọ́n sì ń fi orúkọ rẹ̀ búra wọ́n sì tún ń fi oriṣa Milikomu búra;
6. àwọn tí wọ́n ti pada lẹ́yìn OLUWA, tí wọn kò wá a, tí wọn kì í sì í wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀.”
7. Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA Ọlọrun! Nítorí ọjọ́ OLUWA súnmọ́lé; OLUWA ti ṣètò ẹbọ kan, ó sì ti ya àwọn kan sọ́tọ̀, tí yóo pè wá jẹ ẹ́.
8. Ní ọjọ́ ìrúbọ OLUWA, “N óo fi ìyà jẹ àwọn alákòóso ati àwọn ọmọ ọba, ati àwọn tí ń fi aṣọ orílẹ̀-èdè mìíràn ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́.
9. Ní ọjọ́ náà, n óo jẹ àwọn tí ń fo ẹnu ọ̀nà kọjá bí àwọn abọ̀rìṣà níyà, ati àwọn tí ń fi ìwà ipá, ati olè jíjà kó nǹkan kún ilé oriṣa wọn.”