8. Iranṣẹ náà dá Saulu lóhùn, ó ní, “Mo ní idamẹrin owó ṣekeli fadaka kan lọ́wọ́, n óo fún un, yóo sì sọ ibi tí a óo ti rí wọn fún wa.”
9. (Ní àtijọ́, ní ilẹ̀ Israẹli, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Ọlọrun, yóo wí pé, òun ń lọ sí ọ̀dọ̀ aríran; nítorí àwọn tí àwa ń pè ní wolii lónìí, aríran ni wọ́n ń pè wọ́n nígbà náà.)
10. Saulu bá dá a lóhùn pé, “O ṣeun, jẹ́ kí á lọ.” Wọ́n bá lọ sí ìlú tí eniyan Ọlọrun yìí wà.
11. Bí wọ́n ti ń gun òkè lọ láti wọ ìlú, wọ́n pàdé àwọn ọmọbinrin tí wọ́n ń jáde lọ pọn omi. Wọ́n bi àwọn ọmọbinrin náà pé, “Ǹjẹ́ aríran wà ní ìlú?”
12. Àwọn ọmọbinrin náà dá wọn lóhùn pé, “Ó wà ní ìlú. Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọjá nisinsinyii ni. Bí ó ti ń wọ ìlú bọ̀ tààrà nìyí, ẹ yára lọ bá a. Àwọn eniyan ní ẹbọ kan tí wọn óo rú ní orí òkè lónìí.