Samuẹli Kinni 27:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Dafidi rò ní ọkàn rẹ̀ pé Saulu yóo pa òun ní ọjọ́ kan, nítorí náà ohun tí ó dára jù ni kí òun sá àsálà lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Filistia. Ó ní Saulu yóo dẹ́kun láti máa wá òun kiri ní ilẹ̀ Israẹli, òun óo sì fi bẹ́ẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

2. Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹta (600), bá lọ sọ́dọ̀ Akiṣi, ọmọ Maoki, ọba Gati.

3. Wọ́n ń gbé Gati pẹlu àwọn ará ilé wọn. Àwọn aya Dafidi mejeeji, Ahinoamu ará Jesireeli ati Abigaili ará Kamẹli, opó Nabali, sì wà pẹlu rẹ̀ níbẹ̀.

4. Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi ti sá àsálà lọ sí Gati, ó dẹ́kun láti máa wá a kiri.

Samuẹli Kinni 27