9. Ṣugbọn Dafidi sọ fún Abiṣai pé, “O kò gbọdọ̀ ṣe é ní ibi kan, nítorí ẹni tí ó bá pa ẹni àmì òróró OLUWA yóo jẹ̀bi.
10. Níwọ̀n ìgbà tí OLUWA wà láàyè, OLUWA yóo pa á; tabi kí ọjọ́ ikú rẹ̀ pé, tabi kí ó kú lójú ogun.
11. Kí OLUWA má ṣe jẹ́ kí n pa ẹni àmì òróró rẹ̀. Nítorí náà, jẹ́ kí á mú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ati ìgò omi rẹ̀ kí á sì máa lọ.”
12. Dafidi bá mú ọ̀kọ̀ ati ìgò omi Saulu ní ìgbèrí rẹ̀, òun pẹlu Abiṣai sì jáde lọ. Kò sí ẹnikẹ́ni ninu Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ tí ó mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, tabi tí ó jí nítorí OLUWA kùn wọ́n ní oorun.
13. Dafidi kọjá sí òdìkejì àfonífojì ní orí òkè níbi tí ó jìnnà díẹ̀.
14. Ó sì ké sí àwọn ọmọ ogun Saulu ati Abineri pé, “Abineri! Ǹjẹ́ ò ń gbọ́ ohùn mi bí!”Abineri sì dáhùn pé, “Ìwọ ta ni ń pariwo! Tí o fẹ́ jí ọba?”
15. Dafidi dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ìwọ kọ́ ni alágbára jùlọ ní Israẹli? Kí ló dé tí o kò dáàbò bo ọba, oluwa rẹ? Láìpẹ́ yìí ni ẹnìkan wọ inú àgọ́ yín láti pa oluwa rẹ.
16. Ohun tí o ṣe yìí kò dára, mo fi OLUWA ṣe ẹ̀rí pé, ó yẹ kí o kú, nítorí pé o kò dáàbò bo oluwa rẹ, ẹni àmì òróró OLUWA. Níbo ni ọ̀kọ̀ ọba wà? Ibo sì ni ìgò omi tí ó wà ní ìgbèrí rẹ̀ wà pẹlu?”
17. Saulu mọ̀ pé Dafidi ni ó ń sọ̀rọ̀, ó bá bèèrè pé, “Dafidi ọmọ mi, ṣé ìwọ ni ò ń sọ̀rọ̀?”Dafidi dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, oluwa mi.
18. Kí ló dé tí o fi ń lépa èmi iranṣẹ rẹ? Kí ni mo ṣe? Kí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ mi?
19. Oluwa mi, gbọ́ ohun tí èmi iranṣẹ rẹ fẹ́ sọ. Bí ó bá jẹ́ pé OLUWA ni ó gbé ọ dìde sí mi, kí ó gba ẹbọ ẹ̀bẹ̀, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé eniyan ni, kí ègún OLUWA wá sórí olúwarẹ̀, nítorí wọ́n lé mi jáde, kí n má baà ní ìpín ninu ilẹ̀ ìní tí OLUWA fún àwọn eniyan rẹ̀. Wọ́n ń sọ fún mi pé kí n lọ máa bọ oriṣa.