Samuẹli Kinni 19:19-24 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi wà ní Naioti ní Rama,

20. ó rán àwọn iranṣẹ láti mú un. Nígbà tí àwọn iranṣẹ náà rí ẹgbẹ́ àwọn wolii tí wọn ń jó, tí wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, pẹlu Samuẹli ní ààrin wọn gẹ́gẹ́ bí olórí wọn, ẹ̀mí Ọlọrun bà lé àwọn iranṣẹ náà, àwọn náà bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀.

21. Nígbà tí Saulu gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn oníṣẹ́ rẹ̀, ó rán àwọn mìíràn, àwọn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀. Ó rán àwọn oníṣẹ́ ní ìgbà kẹta, àwọn náà tún ń sọ àsọtẹ́lẹ̀.

22. Òun pàápàá dìde ó lọ sí Rama. Nígbà tí ó dé etí kànga jíjìn tí ó wà ní Seku, ó bèèrè ibi tí Samuẹli ati Dafidi wà. Wọ́n sì sọ fún un wí pé, wọ́n wà ní Naioti ti Rama.

23. Ó kúrò níbẹ̀, ó sì lọ sí Naioti ti Rama, bí ó ti ń lọ, ẹ̀mí Ọlọrun bà lé e, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ títí tí ó fi dé Naioti.

24. Ó bọ́ aṣọ rẹ̀, ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ níwájú Samuẹli. Ó sùn ní ìhòòhò ní ọ̀sán ati òru ọjọ́ náà. Àwọn eniyan sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ wí pé, “Àbí Saulu náà ti di wolii?”

Samuẹli Kinni 19