41. Filistini náà sì ń rìn bọ̀ wá pàdé Dafidi; ẹni tí ń ru asà rẹ̀ sì wà níwájú rẹ̀.
42. Nígbà tí ó rí Dafidi dáradára, ó wò ó pé ọmọ kékeré kan lásán, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́wà ni, nítorí náà, ó fojú tẹmbẹlu rẹ̀.
43. Ó bi Dafidi pé, “Ṣé ajá ni mí ni, tí o fi ń mú ọ̀pá tọ̀ mí bọ̀?” Ó fi Dafidi bú ní orúkọ oriṣa rẹ̀,
44. ó sì wí pé, “Sún mọ́ mi níhìn-ín, n óo sì fi ẹran ara rẹ fún àwọn ẹyẹ ati ẹranko jẹ.”
45. Dafidi dáhùn pé, “Ìwọ ń bọ̀ wá bá mi jà pẹlu idà ati ọ̀kọ̀, ṣugbọn èmi ń bọ̀ wá pàdé rẹ ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun Israẹli, tí ò ń pẹ̀gàn.