4. Akikanju ọkunrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Goliati, ará ìlú Gati, jáde wá láti ààrin àwọn Filistini. Ó ga ní ìwọ̀n igbọnwọ mẹfa ati ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan.
5. Ó dé àṣíborí bàbà, ó wọ ẹ̀wù tí wọ́n fi bàbà pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ẹẹdẹgbaata (5,000) ṣekeli.
6. Ó ní ihamọra bàbà ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì gbé ọ̀kọ̀ bàbà kan sí èjìká rẹ̀.
7. Ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì dàbí igi òfì, irin tí ó wà lórí ọ̀kọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹta (600) òṣùnwọ̀n ṣekeli. Ẹni tí ń ru asà rẹ̀ sì ń rìn níwájú rẹ̀.
8. Goliati dúró, ó sì kígbe pe àwọn ọmọ Israẹli, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi kó ara yín jọ láti jagun? Ṣebí Filistini kan ni èmi, ẹ̀yin náà sì jẹ́ ẹrú Saulu? Ẹ̀yin ẹ yan ọkunrin kan láàrin yín tí yóo sọ̀kalẹ̀ wá bá mi jà.
9. Bí ó bá pa mí, a óo di ẹrú yín. Ṣugbọn bí mo bá ṣẹgun rẹ̀, tí mo sì pa á, ẹ óo di ẹrú wa.
10. Mo pe ẹ̀yin ọmọ ogun Israẹli níjà lónìí, ẹ yan ọkunrin kan, kí ó wá bá mi jà.”
11. Nígbà tí Saulu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbọ́, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi.
12. Ọmọ Jese ni Dafidi, ará Efurati ní Bẹtilẹhẹmu ti Juda; Ọmọkunrin mẹjọ ni Jese bí, ó sì ti di arúgbó nígbà tí Saulu jọba.
13. Àwọn mẹta tí wọ́n dàgbà jùlọ láàrin àwọn ọmọ Jese bá Saulu lọ sójú ogun. Eliabu ni orúkọ àkọ́bí. Abinadabu ni ti ekeji, Ṣama sì ni ti ẹkẹta.
14. Dafidi ni àbíkẹ́yìn patapata; àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mẹta náà sì wà ninu àwọn ọmọ ogun Saulu.
15. Dafidi a máa lọ sí Bẹtilẹhẹmu nígbà gbogbo láti tọ́jú agbo ẹran baba rẹ̀.
16. Odidi ogoji ọjọ́ ni Goliati fi pe àwọn ọmọ ogun Israẹli níjà ní àràárọ̀ ati ìrọ̀lẹ́ ìrọ̀lẹ́.
17. Ní ọjọ́ kan, Jese sọ fún Dafidi pé, “Jọ̀wọ́, mú ìwọ̀n efa àgbàdo yíyan kan, ati burẹdi mẹ́wàá yìí lọ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ní ibùdó ogun.
18. Mú wàrà sísè mẹ́wàá yìí lọ́wọ́ fún olórí ogun ikọ̀ wọn, kí o sì bá mi wo alaafia àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ, kí o gba nǹkankan bọ̀ lọ́dọ̀ wọn tí yóo fihàn mí pé alaafia ni wọ́n wà.”