Samuẹli Kinni 17:28-36 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Nígbà tí Eliabu, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àgbà gbọ́ tí ó ń bá àwọn ọkunrin náà sọ̀rọ̀, ó bínú sí Dafidi, ó ní, “Kí ni ìwọ ń wá níbí? Ta ni ó ń tọ́jú àwọn aguntan rẹ ninu pápá? Ìwọ onigbeeraga ati ọlọ́kàn líle yìí, nítorí kí o lè wo ogun ni o ṣe wá síbí.”

29. Dafidi sì dáhùn pé, “Kí ni mo ṣe nisinsinyii? Ṣebí ọ̀rọ̀ lásán ni mò ń sọ.”

30. Dafidi yipada kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn, ó tún bèèrè ìbéèrè kan náà. Àwọn ọkunrin náà sì fún un ní èsì bíi ti iṣaaju.

31. Àwọn ọmọ ogun náà sọ ọ̀rọ̀ tí Dafidi sọ níwájú Saulu, Saulu bá ranṣẹ pè é.

32. Dafidi sọ fún Saulu pé, “Ẹ má bẹ̀rù ọkunrin yìí; èmi, iranṣẹ rẹ óo lọ bá a jà.”

33. Saulu bá sọ fún Dafidi pé, “O kò lè bá Filistini yìí jà, nítorí pé ọmọde ni ọ́, òun sì ti jẹ́ jagunjagun láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.”

34. Dafidi dáhùn pé, “Ìgbàkúùgbà tí èmi iranṣẹ rẹ bá ń ṣọ́ agbo aguntan baba mi, tí kinniun tabi ẹranko beari bá gbé ọ̀kan ninu aguntan náà,

35. n óo tẹ̀lé e lọ, n óo lù ú, n óo sì gba aguntan náà kúrò lẹ́nu rẹ̀. Bí ó bá sì kọjú ìjà sí mi, n óo di ọ̀fun rẹ̀ mú, n óo sì pa á.

36. Èmi iranṣẹ rẹ yìí ti pa àwọn kinniun ati àwọn ẹranko beari rí, aláìkọlà Filistini yìí yóo sì dàbí ọ̀kan ninu wọn, nítorí pé, ó ti pe àwọn ọmọ ogun Ọlọrun alààyè níjà.

Samuẹli Kinni 17