26. Nígbà tí wọ́n wọ inú igbó náà, wọ́n rí i tí oyin ń kán sílẹ̀, ṣugbọn kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè fi ọwọ́ kàn án nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìbúra Saulu.
27. Ṣugbọn Jonatani kò gbọ́ nígbà tí baba rẹ̀ ń fi ìbúra pàṣẹ fún àwọn eniyan náà. Nítorí náà, ó na ọ̀pá tí ó mú lọ́wọ́, ó tì í bọ inú afárá oyin kan, ó sì lá a. Lẹsẹkẹsẹ ojú rẹ̀ wálẹ̀.
28. Ọ̀kan ninu àwọn eniyan náà wí fún un pé, “Ebi ń pa gbogbo wa kú lọ, ṣugbọn baba rẹ ti búra pé, ‘Ègbé ni fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ẹnu kan nǹkankan lónìí.’ ”
29. Jonatani dáhùn pé, “Ohun tí baba mi ṣe sí àwọn eniyan wọnyi kò dára, wò ó bí ojú mi ti wálẹ̀ nígbà tí mo lá oyin díẹ̀.
30. Báwo ni ìbá ti dára tó lónìí, bí ó bá jẹ́ pé àwọn eniyan jẹ lára ìkógun àwọn ọ̀tá wọn tí wọ́n rí. Àwọn ará Filistia tí wọn ìbá pa ìbá ti pọ̀ ju èyí lọ.”