4. Wọn yóo kí ọ, wọn yóo sì fún ọ ní meji ninu burẹdi náà, gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn.
5. Lẹ́yìn náà, lọ sí òkè Ọlọrun ní Gibea Elohimu, ní ibi tí ibùdó àwọn ọmọ ogun Filistini kan wà. Nígbà tí ó bá kù díẹ̀ kí ẹ dé ìlú náà, o óo pàdé ọ̀wọ́ àwọn wolii kan, tí wọn ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti ibi pẹpẹ tí ó wà ní orí òkè. Wọn yóo máa ta hapu, wọn yóo máa lu aro, wọn yóo máa fọn fèrè, wọn yóo máa tẹ dùùrù, wọn yóo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀.
6. Nígbà náà, ẹ̀mí OLUWA yóo bà lé ọ, o óo sì darapọ̀ mọ́ wọn, o óo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀, o óo sì yàtọ̀ patapata sí bí o ti wà tẹ́lẹ̀.
7. Nígbà tí gbogbo nǹkan wọnyi bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, ṣe ohunkohun tí ó bá wá sọ́kàn rẹ, nítorí Ọlọrun wà pẹlu rẹ.
8. Máa lọ sí Giligali ṣiwaju mi. N óo wá bá ọ níbẹ̀ láti rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia. Dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ meje, títí tí n óo fi dé, n óo sì sọ ohun tí o óo ṣe fún ọ.”