Samuẹli Kinni 10:23-26 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Wọ́n sáré lọ mú un jáde láti ibẹ̀. Nígbà tí ó dúró láàrin wọn, kò sí ẹni tí ó ga ju èjìká rẹ̀ lọ ninu wọn.

24. Samuẹli bá wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹni tí OLUWA yàn nìyí. Kò sí ẹnikẹ́ni láàrin wa tí ó dàbí rẹ̀.”Gbogbo àwọn eniyan náà kígbe sókè pé, “Kí ọba kí ó pẹ́.”

25. Samuẹli ṣe àlàyé àwọn ẹ̀tọ́ ati iṣẹ́ ọba fún àwọn eniyan náà. Ó kọ àwọn àlàyé náà sinu ìwé kan, ó sì gbé e siwaju OLUWA. Lẹ́yìn náà, ó ní kí olukuluku máa lọ sí ilé rẹ̀.

26. Saulu náà bá pada lọ sí ilé rẹ̀ ní Gibea. Àwọn akọni ọkunrin bíi mélòó kan tí Ọlọrun ti fi sí ní ọkàn bá Saulu lọ.

Samuẹli Kinni 10