Samuẹli Keji 5:18-25 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Nígbà tí àwọn ará Filistia dé ibi àfonífojì Refaimu, wọ́n dúró níbẹ̀.

19. Dafidi bi OLUWA pé, “Ṣé kí n kọlu àwọn ará Filistia, ṣé o óo fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn?”OLUWA dá a lóhùn pé, “Kọlù wọ́n, n óo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí wọn.”

20. Dafidi bá wá sí Baali Perasimu, ó sì ṣẹgun àwọn ará Filistia níbẹ̀. Ó ní, “Bí ìkún omi tí í ya bèbè rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA fọ́n àwọn ọ̀tá mi ká níwájú mi.” Ó bá pe orúkọ ibẹ̀ ní Baali Perasimu.

21. Níbi tí àwọn ará Filistia ti ń sá lọ, wọ́n gbàgbé àwọn oriṣa wọn sílẹ̀, Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sì kó wọn lọ.

22. Àwọn ará Filistia pada, wọ́n tún dúró sí àfonífojì Refaimu.

23. Dafidi tún tọ OLUWA lọ láti bèèrè ohun tí yóo ṣe. OLUWA dá a lóhùn pé, “Má ṣe kọlù wọ́n níhìn-ín, ṣugbọn múra, kí o yípo lọ sẹ́yìn wọn, kí o sì kọlù wọ́n ní apá òdìkejì àwọn igi basamu.

24. Nígbà tí o bá gbọ́ ìró kan, tí ó bá dàbí ẹni pé, eniyan ń fi ẹsẹ̀ kilẹ̀ lọ lórí àwọn igi, ni kí o tó kọlù wọ́n, nítorí pé, OLUWA ti kọjá lọ níwájú rẹ láti ṣẹgun àwọn ọmọ ogun Filistini.”

25. Dafidi ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un, ó sì pa àwọn ọmọ ogun Filistini láti Geba títí dé Geseri.

Samuẹli Keji 5