Samuẹli Keji 4:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu gbọ́ pé wọ́n ti pa Abineri ní Heburoni, ẹ̀rù bà á gidigidi, ìdààmú sì bá gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

2. Iṣiboṣẹti ní àwọn ìjòyè meji kan, tí wọ́n jẹ́ aṣaaju fún àwọn tí wọ́n máa ń dánà káàkiri. Orúkọ ekinni ni Baana, ti ekeji sì ni Rekabu, ọmọ Rimoni, ará Beeroti, ti ẹ̀yà Bẹnjamini. (Ẹ̀yà Bẹnjamini ni wọ́n ka Beeroti kún.)

3. Àwọn ará Beeroti ti sá lọ sí Gitaimu, ibẹ̀ ni wọ́n sì ń gbé títí di òní olónìí.

4. Jonatani ọmọ Saulu ní ọmọkunrin kan, tí ó yarọ, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mẹfiboṣẹti. Ọmọ ọdún marun-un ni, nígbà tí wọ́n mú ìròyìn ikú Saulu ati ti Jonatani wá, láti ìlú Jesireeli; ni olùtọ́jú rẹ̀ bá gbé e sá kúrò. Ibi tí ó ti ń fi ìkánjú gbé ọmọ náà sá lọ, ó já ṣubú, ó sì fi bẹ́ẹ̀ yarọ.

5. Ní ọjọ́ kan, Rekabu ati Baana, àwọn ọmọ Rimoni ará Beeroti, gbéra, wọ́n lọ sí ilé Iṣiboṣẹti, wọ́n débẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀sán, ní àkókò tí Iṣiboṣẹti ń sun oorun ọ̀sán lọ́wọ́.

Samuẹli Keji 4