5. Wọ́n ré odò Jọdani kọjá, wọ́n pàgọ́ sí ìhà gúsù Aroeri, ìlú tí ó wà ní ààrin àfonífojì, ní agbègbè Gadi. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti lọ sí ìhà àríwá, títí dé Jaseri.
6. Wọ́n lọ sí Gileadi, ati sí Kadeṣi ní ilẹ̀ àwọn ará Hiti. Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sí Dani. Láti Dani, wọ́n lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn títí dé Sidoni.
7. Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sí apá gúsù. Wọ́n dé ìlú olódi ti Tire, títí lọ dé gbogbo ìlú àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Kenaani. Níkẹyìn, wọ́n wá sí Beeriṣeba ní apá ìhà gúsù Juda.
8. Oṣù mẹsan-an ati ogúnjọ́ ni ó gbà wọ́n láti lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Israẹli, lẹ́yìn náà, wọ́n pada sí Jerusalẹmu.
9. Joabu sọ iye àwọn eniyan tí ó kà fún ọba: Ogoji ọ̀kẹ́ (800,000) ni àwọn ọkunrin tí wọ́n tó ogun jà ní ilẹ̀ Israẹli, àwọn ti ilẹ̀ Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹẹdọgbọn (500,000).
10. Ṣugbọn lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ka àwọn eniyan náà tán, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dà á láàmú. Ó bá wí fún OLUWA pé, “Ohun tí mo ṣe yìí burú gan-an, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá gbáà ni. Jọ̀wọ́, dáríjì èmi iranṣẹ rẹ, ìwà òmùgọ̀ gbáà ni mo hù.”
11. Nígbà tí Dafidi jí ní òwúrọ̀, OLUWA rán wolii Gadi, aríran rẹ̀ sí i pé,
12. “Lọ sọ fún Dafidi pé mo fi nǹkan mẹta siwaju rẹ̀; kí ó yan ọ̀kan tí ó fẹ́ kí n ṣe sí òun ninu mẹtẹẹta.”
13. Gadi bá lọ sọ ohun tí OLUWA wí fún Dafidi. Ó bèèrè pé, “Èwo ni o fẹ́ yàn ninu mẹtẹẹta yìí, ekinni, kí ìyàn mú ní ilẹ̀ rẹ fún ọdún mẹta; ekeji, kí o máa sá fún àwọn ọ̀tá rẹ fún oṣù mẹta; ẹkẹta, kí àjàkálẹ̀ àrùn jà fún ọjọ́ mẹta ní gbogbo ilẹ̀ rẹ? Rò ó dáradára, kí o sì sọ èyí tí o fẹ́, kí n lọ sọ fún OLUWA.”