15. Àwọn mejila bá jáde láti ẹ̀gbẹ́ kinni keji; àwọn mejila ẹ̀gbẹ́ kan dúró fún ẹ̀yà Bẹnjamini ati Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu, wọ́n sì bá àwọn iranṣẹ Dafidi mejila, tí wọ́n jáde láti inú ẹ̀yà Juda jà.
16. Ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ẹ̀gbẹ́ kinni, dojú kọ ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ẹ̀gbẹ́ keji, wọ́n sì gbá ara wọn lórí mú. Ẹnìkínní ti idà rẹ̀ bọ ẹnìkejì rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́, àwọn mẹrẹẹrinlelogun ṣubú lulẹ̀, wọ́n sì kú. Ìdí nìyí tí wọ́n fi sọ ibẹ̀ ní Helikati-hasurimu. Ìtumọ̀ rẹ̀ ni “Pápá Idà”; ó wà ní Gibeoni.
17. Ogun gbígbóná bẹ́ sílẹ̀ ní ọjọ́ náà, ṣugbọn àwọn eniyan Dafidi ṣẹgun Abineri ati àwọn eniyan Israẹli.
18. Àwọn ọmọ Seruaya mẹtẹẹta, Joabu, Abiṣai, ati Asaheli, wà lójú ogun náà. Ẹsẹ̀ Asaheli yá nílẹ̀ pupọ, àfi bí ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín.
19. Asaheli bẹ̀rẹ̀ sí lé Abineri lọ, bí ó sì ti ń lé e lọ, kò wo ọ̀tún, bẹ́ẹ̀ ni kò wo òsì.