Samuẹli Keji 16:22-23 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Wọ́n bá pàgọ́ kan fún Absalomu, lórí òrùlé ààfin, ó wọlé lọ bá àwọn obinrin baba rẹ̀ lójú gbogbo àwọn eniyan, ó sì bá wọn lòpọ̀.

23. Ní àkókò náà, ìmọ̀ràn tí Ahitofeli bá dá, ni àwọn eniyan máa ń gbà, bí ẹni pé Ọlọrun gan-an ni ó ń sọ̀rọ̀; Dafidi ati Absalomu pàápàá a máa tẹ̀lé ìmọ̀ràn rẹ̀.

Samuẹli Keji 16