Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ bá ń bá tiwọn lọ, Ṣimei sì ń tẹ̀lé wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji òkè náà, bí ó ti ń tẹ̀lé wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ṣépè, ó ń sọ òkúta lù ú, ó sì ń da erùpẹ̀ sí wọn lára.