35. Ṣebí Sadoku ati Abiatari, àwọn alufaa mejeeji wà níbẹ̀, gbogbo ohun tí o bá ti gbọ́ ninu ààfin ọba ni kí o máa sọ fún wọn.
36. Àwọn ọmọ wọn mejeeji, Ahimaasi ati Jonatani wà lọ́dọ̀ wọn. Gbogbo ohun tí ẹ bá gbọ́, kí ẹ máa rán wọn sí mi.”
37. Huṣai bá pada, ó dé Jerusalẹmu bí Absalomu tí ń wọ ìlú bọ̀ gẹ́lẹ́.