1. OLUWA rán Natani wolii sí Dafidi. Natani bá tọ Dafidi lọ, ó sì sọ fún un pé, “Àwọn ọkunrin meji wà ninu ìlú kan, ọ̀kan jẹ́ ọlọ́rọ̀, ekeji sì jẹ́ talaka.
2. Ọkunrin ọlọ́rọ̀ yìí ní ọpọlọpọ agbo mààlúù, ati agbo aguntan.
3. Ṣugbọn ọkunrin talaka yìí kò ní nǹkankan, àfi ọmọ aguntan kékeré kan tí ó rà, tí ó sì ń tọ́jú títí tí ó fi dàgbà ninu ilé rẹ̀, pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀. Ninu oúnjẹ tí òun pàápàá ń jẹ ni ó ti ń fún un jẹ, igbá tí ọkunrin yìí fi ń mu omi ni ó fi ń bu omi fún ọmọ aguntan rẹ̀ mu. A sì máa gbé e jókòó lórí ẹsẹ̀, bí ẹni pé ọmọ rẹ̀ gan-an ni.