9. Saulu bá wí fún mi pé, ‘Sún mọ́ mi níhìn-ín, kí o pa mí, nítorí pé mo ti fara gbọgbẹ́, mò ń jẹ̀rora gidigidi, ṣugbọn ẹ̀mí mi ṣì wà sibẹ.’
10. Mo bá súnmọ́ Saulu, mo sì pa á. Nítorí mo mọ̀ pé, tí ó bá kúkú ṣubú lulẹ̀, yóo kú náà ni. Mo bá ṣí adé orí rẹ̀, mo sì bọ́ ẹ̀gbà ọrùn ọwọ́ rẹ̀. Àwọn ni mo kó wá fún ọ yìí, Dafidi, oluwa mi.”
11. Ni Dafidi ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá fa aṣọ wọn ya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn.
12. Wọ́n ṣọ̀fọ̀, wọ́n sọkún, wọ́n sì gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́; nítorí Saulu ati Jonatani, ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ Israẹli, eniyan OLUWA nítorí pé ọpọlọpọ wọn ni wọ́n ti pa lójú ogun.