14. Nígbà tí àkókò oúnjẹ tó, Boasi pe Rutu, ó ní, “Wá jẹun, kí o fi òkèlè rẹ bọ inú ọtí kíkan.” Rutu bá jókòó lọ́dọ̀ àwọn tí wọn ń kórè ọkà, Boasi gbé ọkà yíyan nawọ́ sí i; ó sì jẹ àjẹyó ati àjẹṣẹ́kù.
15. Nígbà tí Rutu dìde, láti tún máa ṣa ọkà, Boasi pàṣẹ fún àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí ó máa ṣa ọkà láàrin àwọn ìtí ọkà tí ẹ dì jọ, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ yọ ọ́ lẹ́nu.
16. Kí ẹ tilẹ̀ fa ọkà yọ fún un ninu ìtí, kí ẹ sì tún fi í sílẹ̀ láti ṣa ọkà, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ yọ ọ́ lẹ́nu.”
17. Rutu bá tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣa ọkà. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ó pa ọkà tí ó ṣà, ohun tí ó rí tó ìwọ̀n efa ọkà baali kan.
18. Ó gbé e, ó sì lọ sílé. Ó fi ọkà tí ó rí han ìyá ọkọ rẹ̀, ó sì fún un ní oúnjẹ tí ó jẹ kù.
19. Ìyá ọkọ rẹ̀ bi í léèrè, ó ní, “Níbo ni o ti ṣa ọkà lónìí, níbo ni o sì ti ṣiṣẹ́? OLUWA yóo bukun ẹni tí ó ṣàkíyèsí rẹ.”Rutu bá sọ inú oko ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ fún ìyá ọkọ rẹ̀, ó ní, “Inú oko ọkunrin kan tí wọ́n ń pè ní Boasi ni mo ti ṣa ọkà lónìí.”
20. Naomi dáhùn, ó ní, “Kí OLUWA tí kì í gbàgbé láti ṣàánú ati òkú ọ̀run, ati alààyè bukun Boasi.” Naomi bá ṣe àlàyé fún Rutu pé, ẹbí àwọn ni Boasi, ati pé ọ̀kan ninu àwọn tí ó súnmọ́ wọn pẹ́kípẹ́kí ni.
21. Rutu tún fi kún un fún Naomi pé, “Boasi tilẹ̀ tún wí fún mi pé, n kò gbọdọ̀ jìnnà sí àwọn iranṣẹ òun títí tí wọn yóo fi parí ìkórè ọkà Baali rẹ̀.”
22. Naomi dáhùn, ó ní, “Ó dára, máa bá àwọn ọmọbinrin rẹ̀ lọ, ọmọ mi, kí wọ́n má baà yọ ọ́ lẹ́nu bí o bá lọ sinu oko ọkà ẹlòmíràn.”
23. Rutu bá ń bá àwọn ọmọbinrin Boasi lọ láti ṣa ọkà títí wọ́n fi parí ìkórè ọkà Baali, ó sì ń gbé ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ̀.