1. Nítorí náà, mo bẹ àwọn àgbà láàrin yín, alàgbà ni èmi náà, ati ẹlẹ́rìí ìyà Kristi, n óo sì ní ìpín ninu ògo tí yóo farahàn.
2. Mo bẹ̀ yín pé kí ẹ ṣe ìtọ́jú ìjọ Ọlọrun tí ẹ wà ninu rẹ̀. Ẹ máa ṣe iṣẹ́ yín bí alabojuto. Kì í ṣe àfipáṣe ṣugbọn tinútinú bí Ọlọrun ti fẹ́. Ẹ má ṣe é nítorí ohun tí ẹ óo rí gbà níbẹ̀, ṣugbọn kí ẹ ṣe é pẹlu ìtara àtọkànwá.
3. Ẹ má ṣe é bí ẹni tí ó fẹ́ jẹ́ aláṣẹ lórí àwọn tí ó wà lábẹ́ yín ṣugbọn ẹ ṣe é bí àpẹẹrẹ fún ìjọ.
4. Nígbà tí Olú olùṣọ́-aguntan bá dé, ẹ óo gba adé ògo tí kì í ṣá.
5. Bákan náà, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ máa tẹríba fún àwọn àgbà. Gbogbo yín, ẹ gbé ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ wọ̀, bí ẹ ti ń bá ara yín lò, nítorí,“Ọlọrun lòdì sí àwọn onigbeeraga,ṣugbọn a máa fi ojurere wo àwọn onírẹ̀lẹ̀.”
6. Nítorí náà, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ Ọlọrun tí ó lágbára, yóo gbe yín ga ní àkókò tí ó bá wọ̀.
7. Ẹ kó gbogbo ìpayà yín tọ̀ ọ́ lọ, nítorí ìtọ́jú yín jẹ ẹ́ lógún.
8. Ẹ ṣọ́ra. Ẹ dira yín gírí, Èṣù tíí ṣe ọ̀tá yín, ń rìn kiri bíi kinniun tí ń bú ramúramù, ó ń wá ẹni tí yóo pa jẹ.
9. Ẹ takò ó pẹlu igbagbọ tí ó dúró gbọningbọnin. Kí ẹ mọ̀ pé àwọn onigbagbọ ẹgbẹ́ yín ń jẹ irú ìyà kan náà níwọ̀n ìgbà tí wọ́n wà ninu ayé.