14. tabi aṣojú ọba gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó rán láti jẹ àwọn tí ó bá ń ṣe burúkú níyà, ati láti yin àwọn tí ó bá ń ṣe rere.
15. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ Ọlọrun pé nípa ìwà rere yín, kí kẹ́kẹ́ pamọ́ àwọn aṣiwèrè ati àwọn òpè lẹ́nu.
16. Ẹ máa hùwà bí ẹni tí ó ní òmìnira, ṣugbọn kì í ṣe òmìnira láti bo ìwà burúkú mọ́lẹ̀. Ẹ máa hùwà bí iranṣẹ Ọlọrun.
17. Ẹ máa yẹ́ gbogbo eniyan sí. Ẹ máa fẹ́ràn àwọn onigbagbọ. Ẹ bẹ̀rù Ọlọrun. Ẹ máa bu ọlá fún ọba.
18. Ẹ̀yin ọmọ-ọ̀dọ̀, ẹ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ọ̀gá yín ninu gbogbo nǹkan pẹlu ìbẹ̀rù, kì í ṣe fún àwọn ọ̀gá tí ó ní inú rere, tí wọ́n sì ń ṣe ẹ̀tọ́ si yín nìkan, ṣugbọn fún àwọn tí wọ́n rorò pẹlu.
19. Nítorí ó dára kí eniyan farada ìyà tí kò tọ́ sí i tí ó bá ronú ti Ọlọrun.
20. Nítorí ẹ̀yẹ wo ni ó wà ninu pé ẹ ṣe àìdára, wọ́n lù yín, ẹ wá faradà á? Ṣugbọn tí ẹ bá ń ṣe dáradára, tí ẹ jìyà tí ẹ faradà á, èyí jẹ́ ẹ̀yẹ lójú Ọlọrun.
21. Nítorí ìdí èyí ni a fi pè yín, nítorí Kristi jìyà nítorí yín, ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fun yín, pé kí ẹ tẹ̀lé àpẹẹrẹ òun.