14. Nítorí mo mọ̀ pé láìpẹ́ n óo bọ́ àgọ́ ara mi sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Oluwa wa Jesu Kristi ti fihàn mí.
15. Ṣugbọn mò ń làkàkà pé nígbà tí mo bá lọ tán, kí ẹ ní ohun tí ẹ óo fi máa ṣe ìrántí nǹkan wọnyi nígbà gbogbo.
16. Kì í ṣe ìtàn àròsọ ni a gbójú lé nígbà tí a sọ fun yín nípa agbára ati wíwá Oluwa wa Jesu Kristi, ṣugbọn ẹlẹ́rìí ọlá ńlá rẹ̀ ni a jẹ́.
17. Nítorí a rí i nígbà tí ó gba ọlá ati ògo lọ́dọ̀ Ọlọrun Baba, nígbà tí ó gbọ́ ohùn láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ọlá ati ògo yẹ fún, tí ó wí pé,“Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi,inú mi dùn sí ọ.”
18. Àwa fúnra wa gbọ́ ohùn yìí nígbà tí ó wá láti ọ̀run nítorí a wà pẹlu rẹ̀ lórí òkè mímọ́ nígbà náà.
19. A tún rí ẹ̀rí tí ó dájú ninu àsọtẹ́lẹ̀ àwọn wolii, pé, kí ẹ ṣe akiyesi ọ̀rọ̀ yìí, nítorí ó dàbí fìtílà tí ń tàn ninu òkùnkùn, títí ilẹ̀ yóo fi mọ̀, títí ìràwọ̀ òwúrọ̀ yóo fi tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ sinu ọkàn yín.