Orin Dafidi 96:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ kọ orin titun sí OLUWA;gbogbo ayé, ẹ kọ orin sí OLUWA.

2. Ẹ kọ orin sí OLUWA, ẹ yin orúkọ rẹ̀;ẹ sọ nípa ìgbàlà rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́.

3. Ẹ kéde ògo rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;ẹ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan.

Orin Dafidi 96