1. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á kọrin sí OLUWA;ẹ jẹ́ kí á hó ìhó ayọ̀ sí Olùdáàbòbò ati ìgbàlà wa!
2. Ẹ jẹ́ kí á wá siwaju rẹ̀ pẹlu ọpẹ́;ẹ jẹ́ kí á fi orin ìyìn hó ìhó ayọ̀ sí i.
3. Nítorí pé Ọlọrun tí ó tóbi ni OLUWA,ọba tí ó tóbi ni, ó ju gbogbo oriṣa lọ.
4. Ìkáwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà;gíga àwọn òkè ńlá wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pẹlu.
5. Tirẹ̀ ni òkun, nítorí pé òun ni ó dá a;ọwọ́ rẹ̀ ni ó sì fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.