17. Bí kì í bá ṣe pé OLUWA ràn mí lọ́wọ́,ǹ bá ti dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní isà òkú.
18. Nígbà tí mo rò pé, “Ẹsẹ̀ mi ti yọ̀,”OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ni ó gbé mi ró.
19. Nígbà tí àìbàlẹ̀ ọkàn mi pọ̀ pupọ,ìwọ ni o tù mí ninu, tí o dá mi lọ́kàn le.
20. Ǹjẹ́ o lè ní àjọṣe pẹlu àwọn ìkà aláṣẹ,àwọn tí ń fi òfin gbé ìwà ìkà ró?