1. OLUWA, ìwọ ni o ti jẹ́ ibi ààbò wa láti ìrandíran.
2. Kí o tó dá àwọn òkè,ati kí o tó dá ilẹ̀ ati ayé,láti ayérayé, ìwọ ni Ọlọrun.
3. O sọ eniyan di erùpẹ̀ pada,o sì wí pé, “Ẹ yipada, ẹ̀yin ọmọ eniyan.”
4. Nítorí pé lójú rẹ, ẹgbẹrun ọdún dàbí àná,tabi bí ìṣọ́ kan ní òru.
5. Ìwọ a máa gbá ọmọ eniyan dànù; wọ́n dàbí àlá,bíi koríko tí ó tutù ní òwúrọ̀;
6. ní òwúrọ̀ á máa gbilẹ̀, á sì máa jí pérépéré;ní ìrọ̀lẹ́ á sá, á sì rọ.
7. Ibinu rẹ pa wá run;ìrúnú rẹ sì bò wá mọ́lẹ̀.