Orin Dafidi 89:25-28 BIBELI MIMỌ (BM)

25. N óo mú ìjọba rẹ̀ gbòòrò dé òkun;agbára rẹ̀ yóo sì tàn dé odò Yufurate

26. Yóo ké pè mí pé, ‘Ìwọ ni Baba mi,Ọlọrun mi, ati Àpáta ìgbàlà mi.’

27. N óo fi ṣe àkọ́bí,àní, ọba tí ó tóbi ju gbogbo ọba ayé lọ.

28. N óo máa fi ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ hàn án títí lae;majẹmu èmi pẹlu rẹ̀ yóo sì dúró ṣinṣin.

Orin Dafidi 89