Orin Dafidi 80:6-10 BIBELI MIMỌ (BM)

6. O ti mú kí àwọn aládùúgbò wa máa jìjàdù lórí wa;àwọn ọ̀tá wa sì ń fi wá rẹ́rìn-ín láàrin ara wọn.

7. Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun;fi ojurere wò wá,kí á lè là.

8. O mú ìtàkùn àjàrà kan jáde láti Ijipti;o lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde, o sì gbìn ín.

9. O ro ilẹ̀ fún un;ó ta gbòǹgbò wọlẹ̀, igi rẹ̀ sì gbilẹ̀.

10. Òjìji rẹ̀ bo àwọn òkè mọ́lẹ̀,ẹ̀ka rẹ sì bo àwọn igi kedari ńláńlá;

Orin Dafidi 80