5. O ti fi omijé bọ́ wọn bí oúnjẹ,o sì ti fún wọn ní omijé mu ní àmuyó.
6. O ti mú kí àwọn aládùúgbò wa máa jìjàdù lórí wa;àwọn ọ̀tá wa sì ń fi wá rẹ́rìn-ín láàrin ara wọn.
7. Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun;fi ojurere wò wá,kí á lè là.
8. O mú ìtàkùn àjàrà kan jáde láti Ijipti;o lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde, o sì gbìn ín.
9. O ro ilẹ̀ fún un;ó ta gbòǹgbò wọlẹ̀, igi rẹ̀ sì gbilẹ̀.
10. Òjìji rẹ̀ bo àwọn òkè mọ́lẹ̀,ẹ̀ka rẹ sì bo àwọn igi kedari ńláńlá;
11. àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tàn kálẹ̀ títí kan òkun,àwọn èèhù rẹ̀ sì kan odò ńlá.
12. Kí ló dé tí o fi wó ògiri ọgbà rẹ̀,tí gbogbo àwọn tí ń kọjá lọsì fi ń ká èso rẹ̀?
13. Àwọn ìmàdò inú ìgbẹ́ ń jẹ ẹ́ ní àjẹrun,gbogbo àwọn nǹkan tí ń káàkiri ninu oko sì ń jẹ ẹ́.
14. Jọ̀wọ́ tún yipada, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun!Bojúwolẹ̀ láti ọ̀run, kí o sì wò ó;kí o sì tọ́jú ìtàkùn àjàrà yìí,