1. Dẹtí sílẹ̀, ìwọ olùṣọ́-aguntan Israẹli,Ìwọ tí ò ń tọ́jú àwọn ọmọ Josẹfu bí agbo ẹran.Ìwọ tí o gúnwà láàrin àwọn kerubu, yọ bí ọjọ́
2. níwájú Efuraimu ati Bẹnjamini ati Manase.Sọ agbára rẹ jí,kí o sì wá gbà wá là.
3. Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun;fi ojurere wò wá,kí á le gbà wá là.
4. OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun,yóo ti pẹ́ tó, tí o óo máa bínú sí aduraàwọn eniyan rẹ?
5. O ti fi omijé bọ́ wọn bí oúnjẹ,o sì ti fún wọn ní omijé mu ní àmuyó.
6. O ti mú kí àwọn aládùúgbò wa máa jìjàdù lórí wa;àwọn ọ̀tá wa sì ń fi wá rẹ́rìn-ín láàrin ara wọn.
7. Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun;fi ojurere wò wá,kí á lè là.
8. O mú ìtàkùn àjàrà kan jáde láti Ijipti;o lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde, o sì gbìn ín.
9. O ro ilẹ̀ fún un;ó ta gbòǹgbò wọlẹ̀, igi rẹ̀ sì gbilẹ̀.