Orin Dafidi 79:7-12 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run;wọ́n sì ti sọ ibùgbé rẹ di ahoro.

8. Má gbẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wa lára wa;yára, kí o ṣàánú wa,nítorí pé a ti rẹ̀ wá sílẹ̀ patapata.

9. Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọrun Olùgbàlà wa,nítorí iyì orúkọ rẹ;gbà wá, sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá,nítorí orúkọ rẹ.

10. Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè yóo fi máa sọ pé,“Níbo ni Ọlọrun wọn wà?”Níṣojú wa, gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ tí a palára àwọn orílẹ̀-èdè!

11. Jẹ́ kí ìkérora àwọn ìgbèkùn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ;gẹ́gẹ́ bí agbára ńlá rẹ,dá àwọn tí a dájọ́ ikú fún sí.

12. OLUWA, san ẹ̀san ẹ̀gàn tí àwọn aládùúgbò wa gàn ọ́,san án fún wọn ní ìlọ́po meje,

Orin Dafidi 79