Orin Dafidi 78:9-12 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Àwọn ọmọ Efuraimu kó ọrun, wọ́n kó ọfà,ṣugbọn wọ́n pẹ̀yìndà lọ́jọ́ ìjà.

10. Wọn kò pa majẹmu Ọlọrun mọ́,wọ́n kọ̀, wọn kò jẹ́ pa òfin rẹ̀ mọ́.

11. Wọ́n gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀,ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe hàn wọ́n.

12. Ní ìṣojú àwọn baba ńlá wọn, ó ṣe ohun ìyanu,ní ilẹ̀ Ijipti, ní oko Soani.

Orin Dafidi 78