59. Nígbà tí Ọlọrun gbọ́, inú bí i gidigidi;ó sì kọ Israẹli sílẹ̀ patapata.
60. Ó kọ ibùgbé rẹ̀ ní Ṣilo sílẹ̀,àní, àgọ́ rẹ̀ láàrin ọmọ eniyan.
61. Ó jẹ́ kí á gbé àmì agbára rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn;ó sì fi ògo rẹ̀ lé ọ̀tá lọ́wọ́.
62. Ó jẹ́ kí á fi idà pa àwọn eniyan rẹ̀;ó sì bínú gidigidi sí àwọn eniyan ìní rẹ̀.
63. Iná run àwọn ọdọmọkunrin wọn;àwọn ọdọmọbinrin wọn kò sì rójú kọrin igbeyawo.
64. Àwọn alufaa kú ikú ogun;àwọn opó wọn kò sì rójú sọkún.
65. Lẹ́yìn náà, OLUWA dìde bí ẹni tají lójú oorun,bí ọkunrin alágbára tí ó mu ọtí yó tí ó ń kígbe.
66. Ó lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ sẹ́yìn;ó dójú tì wọ́n títí ayé.
67. Ó kọ àgọ́ àwọn ọmọ Josẹfu sílẹ̀;kò sì yan ẹ̀yà Efuraimu;
68. ṣugbọn ó yan ẹ̀yà Juda,ó sì yan òkè Sioni tí ó fẹ́ràn.