Orin Dafidi 77:2-5 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi, mo wá OLUWA;ní òru, mo tẹ́wọ́ adura láìkáàárẹ̀,ṣugbọn n kò rí ìtùnú.

3. Mo ronú nípa Ọlọrun títí, mò ń kérora;mo ṣe àṣàrò títí, ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì.

4. OLUWA, o ò jẹ́ kí n dijú wò ní gbogbo òrumo dààmú tóbẹ́ẹ̀ tí n kò le sọ̀rọ̀.

5. Mo ranti ìgbà àtijọ́,mo ranti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn.

Orin Dafidi 77