2. OLUWA ní, “Nígbà tí àkókò tí mo yà sọ́tọ̀ bá tó,n óo ṣe ìdájọ́ pẹlu àìṣojúṣàájú.
3. Nígbà tí ayé bá ń mì síhìn-ín sọ́hùn-ún,ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀;èmi a mú kí òpó rẹ̀ dúró wámúwámú.
4. Èmi a sọ fún àwọn tí ń fọ́nnu pé, ‘Ẹ yé fọ́nnu’;èmi a sì sọ fún àwọn eniyan burúkú pé, ‘Ẹ yé ṣe ìgbéraga.’
5. Ẹ má halẹ̀ ju bí ó ti yẹ lọ,ẹ má sì gbéraga.”
6. Nítorí pé kì í ṣe láti ìlà oòrùn,tabi láti ìwọ̀ oòrùn,bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í ṣe apá gúsù tabi àríwá ni ìgbéga tií wá.
7. Ọlọrun níí dájọ́ bí ó ti wù ú:á rẹ ẹnìkan sílẹ̀, á sì gbé ẹlòmíràn ga.