6. Ìwọ ni mo gbára lé láti inú oyún;ìwọ ni o mú mi jáde láti inú ìyá mi.Ìwọ ni n óo máa yìn nígbà gbogbo.
7. Mo di ẹni àmúpòwe fún ọpọlọpọ eniyan,ṣugbọn ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.
8. Ẹnu mi kún fún ìyìn rẹ,ó kún fún ògo rẹ tọ̀sán-tòru.
9. Má ta mí nù ní ìgbà ogbó mi;má sì gbàgbé mi nígbà tí n kò bá lágbára mọ́.
10. Nítorí pé àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi,àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi ti pàmọ̀ pọ̀,
11. wọ́n ní, “Ọlọrun ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;ẹ lé e, ẹ mú un;nítorí kò sí ẹni tí yóo gbà á sílẹ̀ mọ́.”