8. Mo ti di àlejò lọ́dọ̀ àwọn arakunrin mi,mo sì di àjèjì lọ́dọ̀ àwọn ọmọ ìyá mi.
9. Nítorí pé ìtara ilé rẹ ni ó jẹ mí lógún,ìwọ̀sí àwọn tí ó ń pẹ̀gàn rẹ sì bò mí mọ́lẹ̀.
10. Nígbà tí mo fi omijé gbààwẹ̀,ó di ẹ̀gàn fún mi.
11. Nígbà tí mò ń wọ aṣọ ọ̀fọ̀,mo di ẹni àmúpòwe.
12. Èmi ni àwọn tí ń jókòó lẹ́nu ibodèfi ń ṣe ọ̀rọ̀ sọ;àwọn ọ̀mùtí sì ń fi mí ṣe orin kọ.
13. Ṣugbọn ní tèmi, OLUWA, ìwọ ni mò ń gbadura síní àkókò tí ó bá yẹ, Ọlọrun,ninu ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,ninu agbára ìgbàlà rẹ, Ọlọrun dá mi lóhùn.
14. Yọ mí ninu irà yìí, má jẹ́ kí n rì,gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.
15. Má jẹ́ kí ìgbì omi bò mí mọ́lẹ̀,kí ibú omi má gbé mi mì,kí isà òkú má sì padé mọ́ mi.