Orin Dafidi 69:28-32 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò ninu ìwé ìyè;kí á má sì kọ orúkọ wọn mọ́ ti àwọn olódodo.

29. Ojú ń pọ́n mi, mo sì ń jẹ̀rora;Ọlọrun, jẹ́ kí ìgbàlà rẹ gbé mi lékè!

30. Èmi ó fi orin yin orúkọ Ọlọrun;n óo fi ọpẹ́ gbé e ga.

31. Èyí yóo tẹ́ Ọlọrun lọ́rùn ju akọ mààlúù lọ,àní, akọ mààlúù tòun tìwo ati pátákò rẹ̀.

32. Àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóo rí i,inú wọn yóo dùn;ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá Ọlọrun, ẹ jẹ́ kí ọkàn yín sọjí.

Orin Dafidi 69