21. Dájúdájú, OLUWA yóo fọ́ orí àwọn ọ̀tá rẹ̀;yóo fọ́ àtàrí àwọn tí ń dẹ́ṣẹ̀.
22. OLUWA ní,“N óo kó wọn pada láti Baṣani,n óo kó wọn pada láti inú ibú omi òkun,
23. kí ẹ lè fi ẹsẹ̀ wọ́ àgbàrá ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá yín,kí àwọn ajá yín lè lá ẹ̀jẹ̀ wọn bí ó ti wù wọ́n.”
24. A ti rí ọ, Ọlọrun, bí o tí ń yan lọ,pẹlu ọ̀wọ́ èrò tí ń tẹ̀lé ọ lẹ́yìn.Ẹ wo Ọlọrun mi, ọba mi,bí ó ti ń yan wọ ibi mímọ́ rẹ̀,
25. àwọn akọrin níwájú,àwọn onílù lẹ́yìn,àwọn ọmọbinrin tí ń lu samba láàrin.
26. “Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọrun ninu àwùjọ eniyan,ẹ̀yin ìran Israẹli, ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA.”
27. Ẹ wo Bẹnjamini tí ó kéré jù níwájú,ẹ wo ogunlọ́gọ̀ àwọn ìjòyè Juda,ẹ wo àwọn ìjòyè Sebuluni ati ti Nafutali.
28. Fi agbára rẹ hàn, Ọlọrun,fi agbára tí o ti fi jà fún wa hàn.
29. Nítorí Tẹmpili rẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu,àwọn ọba yóo gbé ẹ̀bùn wá fún ọ.
30. Bá àwọn ẹranko ẹ̀dá tí ń gbé inú èèsún ní Ijipti wí;àwọn akọ mààlúù, láàrin agbo ẹran àwọn orílẹ̀-èdè.Tẹ àwọn tí ó fẹ́ràn owó mọ́lẹ̀;fọ́n àwọn orílẹ̀-èdè tí ó fẹ́ràn ogun ká.
31. Jẹ́ kí àwọn ikọ̀ wá láti Ijipti,kí àwọn ará Kuṣi tẹ́wọ́ adura sí Ọlọrun.