1. Kí Ọlọrun óo ṣàánú wa, kí ó bukun wa;kí ojú rẹ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí wa lára;
2. kí gbogbo ayé lè mọ ọ̀nà rẹ̀;kí gbogbo orílẹ̀-èdè sì mọ ìgbàlà rẹ̀.
3. Jẹ́ kí àwọn eniyan ó máa yìn ọ́, Ọlọrun;jẹ́ kí gbogbo eniyan máa yìn ọ́!
4. Kí inú àwọn orílẹ̀-èdè ó dùn,kí wọn ó máa kọrin ayọ̀,nítorí pé ò ń ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan láìṣe ojuṣaaju;o sì ń tọ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé.
5. Jẹ́ kí àwọn eniyan ó máa yìn ọ́, Ọlọrun;jẹ́ kí gbogbo eniyan máa yìn ọ́!
6. Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀ ìkórè jáde;Ọlọrun, àní Ọlọrun wa, bukun wa.