Orin Dafidi 66:11-14 BIBELI MIMỌ (BM)

11. O jẹ́ kí á bọ́ sinu àwọ̀n;o sì di ẹrù wúwo lé wa lórí.

12. O jẹ́ kí àwọn eniyan máa gùn wá lórí mọ́lẹ̀,a ti la iná ati omi kọjá;sibẹsibẹ o mú wa wá sí ibi tí ilẹ̀ ti tẹ́jú.

13. N óo wá sinu ilé rẹ pẹlu ọrẹ ẹbọ sísun;n óo sì san ẹ̀jẹ́ mi fún ọ.

14. Ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́,tí mo sì fi ẹnu mi sọ nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú.

Orin Dafidi 66