Orin Dafidi 63:6-9 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Nígbà tí mo bá ranti rẹ lórí ibùsùn mi,tí mo bá ń ṣe àṣàrò nípa rẹ ní gbogbo òru;

7. nítorí ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi,lábẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ ni mò ń fi ayọ̀ kọrin.

8. Ẹ̀mí mi rọ̀ mọ́ ọ;ọwọ́ ọ̀tun rẹ ni ó gbé mi ró.

9. Ṣugbọn àwọn tí ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí miyóo sọ̀kalẹ̀ lọ sinu isà òkú.

Orin Dafidi 63