1. Gbọ́ igbe mi, Ọlọrun,fetí sí adura mi.
2. Láti ọ̀nà jíjìn réré ni mo ti ké pè ọ́,nígbà tí àárẹ̀ mú mi.Tọ́ mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ,
3. nítorí ìwọ ni ààbò mi,ìwọ ni ilé ìṣọ́ tí ó lágbáraláti dáàbò bò mí lọ́wọ́ ọ̀tá.
4. Jẹ́ kí n máa gbé inú àgọ́ rẹ títí lae,kí n lè máa wà láìléwu lábẹ́ ààbò ìyẹ́ rẹ.