Orin Dafidi 61:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Gbọ́ igbe mi, Ọlọrun,fetí sí adura mi.

2. Láti ọ̀nà jíjìn réré ni mo ti ké pè ọ́,nígbà tí àárẹ̀ mú mi.Tọ́ mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ,

3. nítorí ìwọ ni ààbò mi,ìwọ ni ilé ìṣọ́ tí ó lágbáraláti dáàbò bò mí lọ́wọ́ ọ̀tá.

Orin Dafidi 61